2 Chronicles 18:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mikaya bá sọ pé, “Mo rí i tí gbogbo ọmọ ogun Israẹli fọ́n káàkiri lórí òkè, bí aguntan tí kò ní olùṣọ́. OLUWA bá sọ pé, ‘Àwọn eniyan wọnyi kò ní olórí. Jẹ́ kí olukuluku máa lọ sí ilé rẹ̀ ní alaafia.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Emi ri gbogbo Israeli fọnka kiri lori awọn òke, bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa: jẹ ki nwọn ki o pada, olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Míkáyà dáhùn, “Mo rí gbogbo Ísírẹ́lì fọ́n káàkiri lórí àwọn òkè, bí àgùntàn tí kò ní olùsọ́. OLÚWA sì wí pé, ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò ní ọ̀gá. Jẹ́ kí olúkúlùkù lọ sí ilé ní àlàáfíà.’ ”