2 Chronicles 18:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Sedekaya, ọmọ Kenaana súnmọ́ Mikaya, ó gbá a létí, ó wí pé, “Nígbà wo ni ẹ̀mí OLUWA fi mí sílẹ̀ tí ó wá ń bá ọ sọ̀rọ̀?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana, sunmọ ọ, o si lù Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà kọja lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Sedékíà ọmọ Kénánà lọ sókè ó sì gbá Míkáyà ní ojú. “Ní ọ̀nà wo níi ẹ̀mí OLÚWA gbà kọjá lọ kúrò lọ́dọ̀ mi láti bá ọ sọ̀rọ̀?” Ó sì bèèrè.