2 Chronicles 18:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mikaya dáhùn pé, “Tí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó sì tún sọ siwaju sí i pé, kí olukuluku fetí sí ohun tí òun wí dáradára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ọdọ mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Míkáyà sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, OLÚWA kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún-un pé, “Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!”