2 Chronicles 18:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ahabu, ọba Israẹli bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé o óo bá mi lọ gbógun ti Ramoti Gileadi?” Jehoṣafati dáhùn pé, “Tìrẹ ni èmi ati àwọn eniyan mi, a óo bá ọ lọ jagun náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ahabu ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati ọba Juda pe, Iwọ o ha ba mi lọ si Ramoti-Gileadi bi? On si da a li ohùn wipe, Emi bi iwọ, ati enia mi bi enia rẹ; awa o pẹlu rẹ li ogun na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì béèrè lọ́wọ́ ọba Jèhóṣáfátì, ọba Júdà pé, “Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi sí Rámótì Gílíádì?” Jehóṣáfátì sì dá a lóhùn pé, “Èmi wà gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe wà, àti àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ àwa yóò pẹ̀lú rẹ ninú ogun naà”