2 Chronicles 18:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ahabu dáhùn pé, “Ó ku ọ̀kan tí à ń pè ní Mikaya, ọmọ Imila tí a lè bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ rere kan kò ti ẹnu rẹ̀ jáde sí mi rí, àfi kìkì burúkú.” Jehoṣafati dáhùn, ó ní, “Má sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan mbẹ sibẹ lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀: nitoriti kò jẹ sọ asọtẹlẹ rere si mi lai, bikòṣe ibi nigbagbogbo: eyini ni Mikaiah, ọmọ Imla. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba ki o má sọ bẹ̃.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Ìsírélì dá Jehóṣáfatì lóhùn pé, “Ọkùnrin kan wà síbẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ì bá tún béèrè lọ́wọ́ OLÚWA, ṣùgbọ́n èmi kórìíra rẹ̀ nítorì kò jẹ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun rere kan nípa mi ṣùgbọ́n bí kò ṣe ohun búburú, ní gbogbo ìgbà òun náà ni Míkáyà ọmọ Ímílà.” “Ọba kò gbọdọ̀ sọ bẹ́ẹ̀,” Jehóṣáfátì sì dá lóhùn.