2 Chronicles 19:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbàkúùgbà tí àwọn arakunrin yín bá mú ẹjọ́ wá siwaju yín láti ìlú kan, kì báà ṣe ti ìtàjẹ̀sílẹ̀, tabi ti nǹkan tí ó jẹ mọ́ òfin, tabi àṣẹ, tabi ìlànà, ẹ níláti ṣe àlàyé fún wọn kí wọ́n má baà jẹ̀bi níwájú OLUWA, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí ẹ̀yin náà ati àwọn arakunrin yín. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ máa ṣe kí ẹ má baà jẹ̀bi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹjọ ki ẹjọ ti o ba si de ọdọ nyin lati ọdọ awọn arakunrin nyin ti ngbe ilu wọn, lãrin ẹ̀jẹ on ẹ̀jẹ, lãrin ofin pẹlu aṣẹ, ìlana ati ẹtọ́, ki ẹnyin ki o kilọ fun wọn, ki nwọn ki o máṣe dẹṣẹ si Oluwa, ibinu a si wá sori nyin, ati sori awọn arakunrin nyin: ẹ ṣe bẹ̃ gẹgẹ, ẹnyin kì yio si jẹbi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní gbogbo ẹjọ́ tí ó bá wà níwájú rẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin yín tí ń gbé ìlú wọn bóyá ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn tàbí ìyókù òfin pẹ̀lú, paálásẹ ìlànà àti ẹ̀tọ́, ìwọ gbọdọ̀ kìlọ̀ fún wọn láti má ṣe dẹ́sẹ̀ sí OLÚWA bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú yóò sì wá sórí yín, àti sórí àwọn arákùnrin. Ṣe èyi, ìwọ kò sì ní dẹ́ṣẹ̀.