2 Chronicles 19:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó kìlọ̀ fún wọn ó ní, “Ẹ ṣọ́ra gan-an, nítorí pé kì í ṣe eniyan ni ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún, OLUWA ni. Ẹ sì ranti pé OLUWA wà lọ́dọ̀ yín bí ẹ ti ń ṣe ìdájọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun awọn onidajọ pe, Ẹ kiyesi ohun ti ẹnyin nṣe! nitori ti ẹnyin kò dajọ fun enia bikòṣe fun Oluwa, ti o wà pẹlu nyin ninu ọ̀ran idajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsí ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún OLÚWA, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́.