2 Chronicles 19:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì ṣọ́ra pẹlu àwọn nǹkan tí ẹ ó máa ṣe, nítorí pé OLUWA Ọlọrun wa kì í yí ìdájọ́ po, kì í ṣe ojuṣaaju, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹ̀ru Oluwa ki o wà lara nyin, ẹ ma ṣọra, ki ẹ si ṣe e; nitoriti kò si aiṣedede kan lọdọ Oluwa Ọlọrun wa, tabi ojuṣaju enia, tabi gbigba abẹtẹlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsin yìí jẹ́kí ìbẹ̀rù OLÚWA kí ó wá sí orí rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú OLÚWA Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”