2 Chronicles 19:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jehoṣafati tún yan àwọn kan ní Jerusalẹmu ninu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn alufaa ati àwọn baálé baálé ní Israẹli, láti máa fi òfin OLUWA ṣe ìdájọ́ ati láti máa yanjú ẹjọ́ tí kò bá di àríyànjiyàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu ni Jerusalemu, Jehoṣafati yàn ninu awọn ọmọ Lefi, ati ninu awọn alufa, ati ninu awọn olori awọn baba Israeli, fun idajọ Oluwa, ati fun ẹjọ; nwọn si ngbe Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, Jéhóṣáfatì yan díẹ̀ lára àwọn Léfì, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Ísírẹ́lì si pípa òfin OLÚWA mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́. Wọn sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.