2 Chronicles 2:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo gbé ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n kori ọkà tí a ti lọ̀, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n baali, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati ọtí, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ìwọ̀n bati òróró fún àwọn iranṣẹ rẹ tí wọn yóo gé àwọn igi náà, wọn óo gbé wọn wá fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wò o, emi o fi fun ilo awọn akégi, ti nké ìti-igi, lọwọ awọn ọmọ-ọdọ rẹ, ẹgbãwa òṣuwọn alikama fun onjẹ, ati ẹgbãwa òṣuwọn barli ati ẹgbãwa bati ọti-waini, ati ẹgbãwa bati ororo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin onígi tí ó ń gé rírẹ́ náà ni ẹgbẹ̀rún kórísì (1,000), àlìkámà ilẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún (20,000) kórísì ti bálì; ẹgbẹ́rùn lọ́nà (20,000) ogún ìwẹ̀ ọtí wáìnì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ìwẹ̀ òróró Ólífì.”