2 Chronicles 2:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó tún fi kún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó dá ọ̀run ati ayé, tí ó fún Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó sì ní òye ati ìmọ̀ láti kọ́ tẹmpili fún OLUWA ati láti kọ́ ààfin fún ara rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Huramu si wipe, Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o da ọrun on aiye, ẹniti o fun Dafidi ọba ni ọlọgbọ́n ọmọ, ti o mọ̀ ọgbọ́n ati oye, ti o le kọ́ ile fun Oluwa, ati ile fun ijọba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hírámì fi kún un pe: “Ìyìn ni fún OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dáfídì ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti àkíyèsí, tí yóò kọ́ ilé fún OLÚWA àti ààfin fún ara rẹ̀.