2 Chronicles 2:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ará Dani ni ìyá rẹ̀, ṣugbọn ará Tire ni baba rẹ̀. Ó mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ wúrà, ati ti fadaka, ti bàbà, ati ti irin; ó sì mọ òkúta, ati igi í gbẹ́. Ó mọ bí a tií ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, aṣọ aláwọ̀ aró, àlàárì, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Ó lè ṣe iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, ó sì lè ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà tí wọ́n bá ní kí ó ṣe pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tìrẹ, ati àwọn òṣìṣẹ́ oluwa mi, Dafidi, baba rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin Dani: baba rẹ̀ si ṣe ọkunrin ara Tire ti o gbọ́ngbọn ati ṣiṣẹ ni wura, ati ni fadakà, ni idẹ, ni irin, ni okuta, ati ni ìti-igi, ni èse-aluko, ni alaró, ati ni ọ̀gbọ daradara, ati òdodó, lati gbẹ́ oniruru ohun gbigbẹ́ pẹlu, ati lati ṣe awari ìmọ ẹrọ gbogbo ti a o fi fun u ṣe, pẹlu awọn ọlọgbọ́n rẹ, ati pẹlu awọn ọlọgbọ́n oluwa mi Dafidi, baba rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ìyá rẹ̀ wá láti Dánì àti tí Baba a rẹ̀ wá láti Tírè. A kọ́ ọ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti igi, àti pẹ̀lú àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ ọ̀run àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó dára. Ó ní ìmọ̀ nínú gbogbo oríṣìí iṣẹ́ fínfín. Ó sì le ṣe àwárí irú ẹ̀yà kẹ́yà tí a bá fún un. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn oníṣọ̀nà pẹ̀lú àwọn ènìyàn OLÚWA mi, Dáfídì baba a rẹ.