2 Chronicles 2:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Solomoni ka gbogbo àwọn àjèjì tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ meje, ó lé ẹgbaaje ati ẹgbẹta (153,600).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si kaye gbogbo awọn ajeji ọkunrin ti o wà ni ilẹ Israeli, gẹgẹ bi kikà ti Dafidi, baba rẹ̀ ti kà wọn; a si ri pe, nwọn jẹ ọkẹ-mẹjọ o di-egbejilelọgbọ̀n.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Ísírẹ́lì lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dáfídì ti ṣe; a sì ka iye wọn sí (153,600) ọ̀kẹ́mẹ́jọ ó dín egbéjì-lélọ́gbọ̀n.