2 Chronicles 2:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó yan ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ninu wọn láti máa ru nǹkan ìkọ́lé, ó ní kí ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) eniyan máa la òkúta, kí ẹẹdẹgbaaji ó lé ẹgbẹta (3,600) jẹ́ alákòóso tí yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si yàn ẹgbã marundilogoji ninu wọn lati ru ẹrù, ati ọkẹ mẹrin lati ṣe aké-okuta li ori òke, ati egbejidilogun alabojuto lati kó awọn enia ṣiṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì yan ẹgbàá márùndínlógójì nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbéjìdínlógún alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́.