2 Chronicles 2:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Solomoni ranṣẹ sí Huramu, ọba Tire pé, “Máa ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Dafidi, baba mi, tí o kó igi kedari ranṣẹ sí i láti kọ́ ààfin rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si ranṣẹ si Huramu, ọba Tire, wipe, Gẹgẹ bi iwọ ti ba Dafidi, baba mi lò, ti iwọ fi igi kedari ṣọwọ si i lati kọ́ ile kan fun u lati ma gbe inu rẹ̀, bẹni ki o ba mi lò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì rán iṣẹ́ yìí sí Hírámíà ọba Tírè: “Rán àwọn igi kédárì sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dáfídì. Nígbà tí ó fi igi kédárì ránsẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé.