2 Chronicles 2:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo fẹ́ kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun mi. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ tí a ó ti máa sun turari olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀. A ó máa mú ẹbọ àkàrà ojoojumọ lọ sibẹ, a ó sì máa rú ẹbọ sísun níbẹ̀ láàárọ̀ ati lálẹ́; ati ní ọjọọjọ́ ìsinmi, ati ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣooṣù, ati ní gbogbo ọjọ́ àjọ̀dún OLUWA Ọlọrun wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún Israẹli títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, emi nkọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun mi, lati yà a si mimọ́ fun u, ati lati sun turari niwaju rẹ̀, ati fun àkara-ifihan igbakugba, ati fun ẹbọsisun li ọwurọ ati li alẹ, li ọjọjọ isimi ati li oṣoṣù titun, ati li apejọ Oluwa Ọlọrun wa; eyi ni aṣẹ fun Israeli titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ OLÚWA Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà-ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún síse ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti òṣùpá tuntun àti ní àpèjọ OLÚWA Ọlọ́run wa. Èyí ni àsẹ fún Ísírẹ́lì láéláé.