2 Chronicles 2:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, fi ẹnìkan ranṣẹ sí mi, tí ó mọ̀ nípa iṣẹ́ wúrà, fadaka, bàbà, ati irin, ẹni tí ó lè ṣiṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ elése àlùkò, ati àlàárì, ati aṣọ aláwọ̀ aró, tí ó sì mọ̀ nípa iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Yóo wà pẹlu àwọn òṣìṣẹ́ tí baba mi ti pèsè sílẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu mi ní Juda ati Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi rán ọkunrin kan si mi ti o gbọ́n lati ṣiṣẹ ni wura, fadakà, ati ni idẹ, ati ni irin, ati ni èse aluko, ati òdodó ati alaró, ti o si le gbọ́ngbọn ati gbẹgi pẹlu awọn ọkunrin ọlọgbọ́n ti o wà lọdọ mi ni Juda ati Jerusalemu, awọn ẹniti Dafidi baba mi ti pese silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní awọ̀ oju ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú isẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Júdà àti Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí Baba à mi Dáfídì pèsè.