2 Chronicles 2:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kó igi kedari, sipirẹsi ati aligumu ranṣẹ sí mi láti Lẹbanoni. Mo mọ̀ pé àwọn iranṣẹ rẹ mọ̀ bí wọ́n ṣe ń gé igi ní Lẹbanoni, àwọn iranṣẹ mi náà yóo sì wà pẹlu wọn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Fi ìti-igi kedari, ati firi, ati algumu ranṣẹ si mi pẹlu, lati Lebanoni wá: emi sa mọ̀ pe awọn iranṣẹ rẹ le gbọ́ngbọn ati ké igi ni Lebanoni; si kiyesi i, awọn ọmọ-ọdọ mi yio wà pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Fi igi òpépé ránṣẹ́ sí mi, pínì àti lígúmì àwọn igi láti Lébánónì, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ.