2 Chronicles 20:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nisinsinyii, wo àwọn ọmọ ogun Amoni, ati ti Moabu ati ti Òkè Seiri, àwọn tí o kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli bá jà nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti, o kò jẹ́ kí wọ́n pa wọ́n run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, kiyesi i, awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, ati awọn ara òke Seiri, ti iwọ kò jẹ ki Israeli gbogun si nigbati nwọn jade ti ilẹ Egipti wá, ṣugbọn nwọn yipada kuro lọdọ wọn, nwọn kò si run wọn;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí àwọn ọkùnrin nìyí láti Ámónì, Móábù àti òkè Séírì, agbègbè ibi ti ìwọ kò ti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyè láti gbógun tì nígbà tí wọn wá láti Éjíbítì; Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn, wọn kò sì pa wọ́n run.