2 Chronicles 20:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun wa, dá wọn lẹ́jọ́. Nítorí pé agbára wa kò tó láti dojú kọ ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun wọn tí wọn ń kó bọ̀ wá bá wa jà. A kò mọ ohun tí a lè ṣe, ìwọ ni a gbójú sókè tí à ń wò.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun wa! Iwọ kì o ha da wọn lẹjọ? nitori awa kò li agbara niwaju ọ̀pọlọpọ nla yi, ti mbọ̀ wá ba wa; awa kò si mọ̀ eyi ti awa o ṣe: ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run wa, ṣé ìwọ kò ní ṣe ìdájọ́ fún wọn? Nítorí àwa kò ní agbára láti dojú kọ àwọn ọ̀pọ̀ ogun ńlá yìí tí ń bọ̀ wá kó wa. Àwa kò mọ̀ ohun tó yẹ ká ṣe, ṣùgbọ́n ojú wa wà ní ọ̀dọ̀ rẹ.”