2 Chronicles 20:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò ní jagun rárá, ẹ sá dúró ní ààyè yín, kí ẹ sì farabalẹ̀, ẹ óo sì rí bí OLUWA yóo ti gba ẹ̀yin ará Juda ati Jerusalẹmu là. Ẹ má fòyà, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín rẹ̀wẹ̀sì, Ẹ lọ kò wọ́n lójú lọ́la, OLUWA yóo wà pẹlu yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò ni ijà li ọ̀ran yi; ẹ tẹgun, ẹ duro jẹ, ki ẹ si ri igbala Oluwa lọdọ nyin, iwọ Juda ati Jerusalemu: ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya: lọla, ẹ jade tọ̀ wọn: Oluwa yio si pẹlu nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin kò ní láti bá ogun yìí jà. Ẹ dúró ní àyè yín; Ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì rí ìgbàlà OLÚWA tí yóò fi fún yín, ìwọ Júdà àti Jérúsálẹ́mù. Ẹ má ṣe bẹ̀rù; Ẹ má sì ṣe fòyà. Ẹ jáde lọ láti lọ dojú kọ wọ́n ní ọ̀la, OLÚWA yóò sì wà pẹ̀lú yín.’ ”