2 Chronicles 20:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn kan wá sọ fún Jehoṣafati pé ogun ńlá kan ń bọ̀ wá jà á láti Edomu ní òdìkejì òkun. Wọ́n sọ pé àwọn ọ̀tá náà ti dé Hasasoni Tamari, (tí a tún ń pè ní Engedi).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn kan wá, nwọn si wi fun Jehoṣafati pe, Ọ̀pọlọpọ enia mbo wá ba ọ lati apakeji okun lati Siria, si kiyesi i, nwọn wà ni Hasason-Tamari ti iṣe Engedi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin wá láti sọ fún Jéhóṣáfátì, “Àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ogun ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Édómù, láti apákejì òkun. Ó ti wà ní Hásásónì Támárì náà” (èyí ni wí pé, Énígédì).