2 Chronicles 20:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Jehoṣafati bá àwọn eniyan rẹ̀ jíròrò tán, ó yan àwọn tí wọn yóo máa kọrin ìyìn sí OLUWA; tí wọn yóo wọ aṣọ mímọ́, tí wọn yóo sì máa yìn ín bí wọn yóo ti máa lọ níwájú ogun, wọn yóo máa kọrin pé, “Ẹ yin OLUWA! Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ dúró laelae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ba awọn enia na gbero, o yàn awọn akọrin si Oluwa, ti yio ma yìn ẹwa ìwa-mimọ́ bi nwọn ti njade lọ niwaju ogun na, ati lati ma wipe, Ẹ yìn Oluwa: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá àwọn ènìyàn náà gbèrò tán, Jéhóṣáfátì yàn wọ́n láti kọrin sí OLÚWA àti láti fi ìyìn fún ẹwà ìwà mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó tì ń jáde lọ sí ìwájú ogun ńlá náà, wí pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA, nítorí àànú rẹ̀ dúró títí láéláé.”