2 Chronicles 20:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Amoni, ati Moabu gbógun ti àwọn ará Òkè Seiri wọ́n sì pa wọ́n run patapata. Lẹ́yìn náà, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Ammoni ati Moabu si dide si awọn ti ngbe òke Seiri, lati pa, ati lati run wọn tũtu: nigbati nwọn si pa awọn ti ngbe òke Seiri run tan, ẹnikini nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Ámónì àti Móábu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Séírì láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin làti òkè Séírì, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run.