2 Chronicles 20:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Jehoṣafati ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti kó ìkógun, wọ́n rí ọpọlọpọ mààlúù, ati ẹrù aṣọ ati nǹkan ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye. Wọ́n kó wọn títí ó fi sú wọn. Odidi ọjọ́ mẹta ni wọ́n fi kó ìkógun nítorí pé ó ti pọ̀ jù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Jehoṣafati ati awọn enia rẹ̀ de lati kó ikogun wọn, nwọn ri lara wọn ọ̀pọlọpọ ọrọ̀, ati okú, ati ohun-elo iyebiye, nwọn si kójọ fun ara wọn, jù eyiti nwọn le kó lọ: nwọn si kó ikogun wọn jọ ni ijọ mẹta, nitoriti o sa papọ̀ju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Jéhóṣáfatì ati àwọn èniyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀.