2 Chronicles 20:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n péjọ ní àfonífojì Beraka. Ibẹ̀ ni wọ́n ti yin OLUWA. Nítorí náà ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pe ibẹ̀ ní Beraka títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọjọ kẹrin nwọn kó ara wọn jọ li afonifoji Ibukún, nitori nibẹ ni nwọn fi ibukún fun Oluwa, nitorina ni a ṣe npe orukọ ibẹ na ni, Afonifoji Ibukún, titi di oni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹ̀rin, wọn kó ara jọpọ̀ ní àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún OLÚWA. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì ìbùkún títí di òní.