2 Chronicles 20:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jehoṣafati kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun, nítorí pé OLUWA ti fún un ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn yipada, gbogbo awọn ọkunrin Juda ati Jerusalemu, ati Jehoṣafati niwaju wọn lati pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀; nitori ti Oluwa ti mu wọn yọ̀ lori awọn ọta wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jéhóṣáfátì, gbogbo àwọn ènìyan Júdà àti Jérúsálẹ́mù padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nítorí OLÚWA ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn.