2 Chronicles 20:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jehoṣafati jọba lórí Juda, ẹni ọdún marundinlogoji ni nígbà tí ó gorí oyè. Gbogbo ọdún tí ó lò lórí oyè jẹ́ ọdún mẹẹdọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Asuba, ọmọ Ṣilihi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoṣafati si jọba lori Juda: o si wà li ẹni ọdun marundilogoji, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹdọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Asuba, ọmọbinrin Ṣilhi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni Jéhóṣáfátì jọba lórí Júdà. Ó sì jẹ́ ẹni ọdún márùndínlógójì. Nígbà tí ó di ọba Júdà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Ásúbà ọmọbìnrin Ṣílíhì.