2 Chronicles 20:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó ní, “OLUWA Ọlọrun àwọn baba wa, ṣebí ìwọ ni Ọlọrun ọ̀run. Ìwọ ni o ni àkóso ìjọba gbogbo orílẹ̀-èdè. Agbára ati ipá wà ní ìkáwọ́ rẹ, kò sì sí ẹni tí ó tó dojú kọ ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Oluwa, Ọlọrun awọn baba wa, iwọ kọ́ ha ni Ọlọrun li ọrun? Iwọ kọ́ ha nṣakoso lori gbogbo ijọba awọn orilẹ-ède? lọwọ rẹ ki agbara ati ipá ha wà, ti ẹnikan kò si, ti o le kò ọ loju?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
O sì wí pé: “OLÚWA, Ọlọ́run àwọn bàba wa, ìwọ kì ha ṣe Ọlọ́run tí ń bẹ ní ọ̀run? Ìwọ ń ṣe alákòóṣo lórí gbogbo ìjọba àwọn orílẹ̀ èdè. Agbára àti ipá ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, kò sì sí ẹnìkan tí ó lè kò ọ́ lójú.