2 Chronicles 20:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí pé tí ibi bá dé bá wa, tabi ìdájọ́, tabi àjàkálẹ̀ àrùn, tabi ìyàn, a óo dúró níwájú ilé yìí ati níwájú rẹ, nítorí orúkọ rẹ wà ninu ilé yìí. A óo ké pè ọ́ ninu ìyọnu wa, o óo gbọ́ tiwa, o óo sì gbà wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ibi ba de si wa, bi idà, ijiya tabi àjakalẹ-àrun, tabi ìyan, bi awa ba duro niwaju ile yi, ati niwaju rẹ, (nitori orukọ rẹ wà ni ile yi): bi a ba ke pè ọ ninu wàhala wa, nigbana ni iwọ o gbọ́, iwọ o si ṣe iranlọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Tí ibi bá wá sí orí wa, bóyá idà ìjìyà tàbí àjàkálẹ̀-àrùn àwọn yóò dúró níwájú rẹ níwájú ilé yìí tí ń jẹ́ orúkọ rẹ, àwa yóò sì sunkún jáde, ìwọ yóò sì gbọ́ wa. Ìwọ yóò sì gbà wá là?’