2 Chronicles 21:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti ìgbà náà ni Edomu ti ń bá Juda ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Ní àkókò kan náà ni Libina ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, ó sì gba òmìnira nítorí pé Jehoramu ti fi ọ̀nà OLUWA àwọn baba rẹ̀ sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sibẹ awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, titi di oni yi. Akokò na pẹlu ni Libna ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ rẹ̀; nitoriti o ti kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Títí di ọjọ́ òní ni Édómù ti wà ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Júdà. Líbínà ṣọ̀tẹ̀ ní àkọ́kọ́ náà, nítorí tí Jéhórámì ti kọ OLÚWA sílẹ̀, Ọlọ́run àwọn baba a rẹ̀.