2 Chronicles 21:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Elija wolii kọ ìwé kan sí Jehoramu, ohun tí ó kọ sinu ìwé náà nìyí: “Gbọ́ bí OLUWA Ọlọrun Dafidi, baba rẹ, ti wí; ó ní, nítorí pé o kò tọ ọ̀nà tí Jehoṣafati baba rẹ tọ̀, tabi ti Asa, baba baba rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwe kan si ti ọdọ Elijah, woli, wá si ọdọ rẹ̀ wipe: Bayi li Oluwa, Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi, nitoriti iwọ kò rìn li ọ̀na Jehoṣafati, baba rẹ, tabi li ọ̀na Asa, ọba Juda;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóhórámì gba ìwé láti ọwọ́ Èlíjà wòlíì, tí ó wí pé: “Èyí ní ohun tí OLÚWA, Ọlọ́run baba à rẹ Dáfídì wí: ‘Ìwọ kò tí ì rìn ní ọ̀nà àwọn baba à rẹ Jèhóṣáfátì tàbí Ásà ọba Júdà.