2 Chronicles 21:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ò ń hùwà bí àwọn ọba Israẹli, o sì ti fa àwọn Juda ati Jerusalẹmu sinu aiṣododo, bí ìdílé Ahabu ti ṣe fún Israẹli. Pataki jùlọ, o pa àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ baba rẹ, tí wọ́n tilẹ̀ sàn jù ọ́ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ti iwọ rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, iwọ si ti mu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu tọ ọ̀na panṣaga, gẹgẹ bi panṣaga ile Ahabu, ati ti iwọ si pa awọn arakunrin ile baba rẹ ti o jẹ ẹni-rere jù iwọ lọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìwọ ti rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì, ìwọ sì ti tọ́ Júdà àti àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti ṣe àgbèrè sí ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe. Ìwọ sì ti pa àwọn arákùnrin rẹ, ẹ̀yà ara ilé bàbá à rẹ, àwọn ọkùnrin tí ó dára jù ọ́ lọ.