2 Chronicles 21:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dó ti Juda, wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ní ààfin lọ, pẹlu àwọn ọmọ Jehoramu ati àwọn iyawo rẹ̀. Kò ku ẹyọ ọmọ kan àfi èyí àbíkẹ́yìn tí ń jẹ́ Ahasaya.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gòke wá si Juda, nwọn si ya wọle, nwọn si kó gbogbo ọrọ̀ ti a ri ni ile ọba ati awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu, ati awọn obinrin rẹ̀, ni igbekun lọ; tobẹ̃ ti a kò ṣẹ́ku ọkunrin kan silẹ fun u, bikòṣe Jehoahasi, abikẹhin ninu awọn ọmọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dojú ìjà kọ Júdà, wọ́n gbàá, wọ́n sì kó gbogbo ọrọ̀ tí a rí ní ilé ọba pẹ̀lú, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin kankan kò kù sílẹ̀ fún un bí kò ṣe Áhásáyà, tí ó kéré jùlọ.