2 Chronicles 21:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn ọdún keji tí àìsàn náà tí ń ṣe é, ìfun rẹ̀ tú síta, ó sì kú ninu ọpọlọpọ ìrora. Wọn kò dá iná ẹ̀yẹ fún un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń ṣe níbi ìsìnkú àwọn baba rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe bẹ̃ bi akokò ti nlọ ati lẹhin ọdun meji, ni ifun rẹ̀ tu jade nitori aìsan rẹ̀, o si kú ninu irora buburu na: awọn enia rẹ̀ kò si ṣe ijona fun u gẹgẹ bi ijona ti awọn baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò kan ní ìparí ọdún kejì, àwọn ìfun rẹ̀ jáde nítorí àrùn náà ó sì kú nínu ìrora ńlá. Àwọn Ènìyàn rẹ̀ kò dá iná láti fi bọlá fún un, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe fún àwọn baba a rẹ̀.