2 Chronicles 21:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni ọdún mejilelọgbọn ni nígbà tí ó gorí oyè, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹjọ. Nígbà tí ó kú, kò sí ẹni tí ó sọkún, tabi tí ó ṣọ̀fọ̀ níbi òkú rẹ̀. Ìlú Dafidi ni wọ́n sin ín sí, ṣugbọn kì í ṣe ní ibojì àwọn ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹni ọdun mejilelọgbọn ni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹjọ ni Jerusalemu, o si fi ilẹ silẹ laiwu ni: nwọn si sìn i ni ilu Dafidi; ṣugbọn kì iṣe ninu iboji awọn ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhórámù jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ní ìgbà tí ó di ọba, Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ. Ó kọjá lọ, kò sí ẹni tí ó kábàámọ̀. A sì sin ín si ìlú ńlá ti Dáfídì. Ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ibojì àwọn ọba.