2 Chronicles 21:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sibẹsibẹ OLUWA kò pa ìdílé Dafidi run nítorí majẹmu tí ó ti bá Dafidi dá, ati ìlérí tí ó ti ṣe pé ọmọ rẹ̀ ni yóo máa wà lórí oyè títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa ile Dafidi run, nitori majẹmu ti o ti ba Dafidi da, ati bi o ti ṣe ileri lati fun u ni imọlẹ kan ati fun awọn ọmọ rẹ̀ lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nítorí tí májẹ̀mú tí OLÚWA ti dá fún Dáfídì kì í ṣe ífẹ́ OLÚWA láti pa ìdílé Dáfídì run ó ti ṣe ìlérí láti tọ́jú fìtílà kan fún un àti àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ títí láé.