2 Chronicles 22:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Jehoṣeba, ọmọbinrin Jehoramu ọba, tí ó jẹ́ iyawo Jehoiada alufaa, gbé Joaṣi ọmọ Ahasaya sá kúrò láàrin àwọn ọmọ ọba tí wọ́n fẹ́ pa, nítorí pé àbúrò rẹ̀ ni Joaṣi yìí. Ó bá fi òun ati olùtọ́jú rẹ̀ pamọ́ sinu yàrá kan. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣeba ṣe gbé ọmọ náà pamọ́ fún Atalaya, tí kò fi rí i pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Jehoṣabeati, ọmọbinrin ọba, mu Joaṣi, ọmọ Ahasiah, o ji i kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa, o fi on ati olutọ rẹ̀ sinu yẹwu Ibusùn. Bẹ̃ni Jehoṣabeati, ọmọbinrin Jehoramu ọba, aya Jehoiada, alufa, (nitori arabinrin Ahasiah li on) o pa a mọ́ kuro lọdọ Ataliah ki o má ba pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Jehóṣẹ́bà ọmọbìnrin ọba Jéhórámù mú Jóásì, ọmọkùnrin Áhásáyà ó sì jíi gbé lọ kúrò láàrin àwọn ọmọ-obìrin ọba, àwọn tí ó kù díẹ̀ kí wọn pa. Wọn gbé òun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù. Nítorí Jèhóṣebà ọmọbìnrin ọba Jehórámì àti ìyàwó àlùfáà Jéhóiádà jẹ́ arábìnrin Áhásáyà. Ó fi ọmọ naà pamọ́ kúrò fún Ataláyà, kí ó má ba à pa á.