2 Chronicles 22:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA bí ìdílé Ahabu ti ṣe, nítorí pé lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, àwọn ará ilé Ahabu ni olùdámọ̀ràn rẹ̀, àwọn ni wọ́n fa ìṣubú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe buburu loju Oluwa bi ile Ahabu: nitori awọn wọnyi li o nṣe igbimọ̀ rẹ̀ lẹhin ikú baba rẹ̀ si iparun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ṣe búburú ní ojú OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, Nítorí lẹ́yìn ikú bàbá a rẹ̀, wọ́n di olùgbani lámọ̀ràn rẹ̀ sí ṣíṣe rẹ̀.