2 Chronicles 22:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó bá pada lọ sí ìlú Jesireeli láti wo ọgbẹ́ tí wọ́n ṣá a lójú ogun ní Rama nígbà tí ó ń bá Hasaeli ọba Siria jagun. Ahasaya, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, sì lọ bẹ̀ ẹ́ wò ní Jesireeli nítorí ara rẹ̀ tí kò yá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si pada lọ iwora ni Jesreeli, nitori ọgbẹ ti a ṣá a ni Rama, nigbati o fi ba Hasaeli, ọba Siria jà. Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, si sọ̀kalẹ lọ iwò Jehoramu, ọmọ Ahabu, ni Jesreeli, nitoriti o ṣaisan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni ó padà sí Jésírẹ́lì láti wo ọgbẹ́ rẹ̀ sàn tí wọ́n ti dá sí i lára ní Rámótì ní ojú ogun rẹ̀ pẹ̀lú Háṣáélì ọba Árámì Nígbà náà, Áhásáyà, ọmọ Jehórámì ọba Júdà lọ sí Jésírẹ́lì láti lọ rí Jórámì ọmọ Áhábù nítorí a ti ṣáa lọ́gbẹ́.