2 Chronicles 22:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun ti pinnu pé ìparun óo bá Ahasaya nígbà tí ó bá lọ bẹ Joramu wò. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, òun pẹlu Joramu lọ pàdé Jehu ọmọ Nimṣi, ẹni tí OLUWA ti yàn pé òun ni yóo pa ìdílé Ahabu run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iparun Ahasiah lati ọwọ Ọlọrun wá ni, nipa wiwá sọdọ Jehoramu: nigbati o si de, o si ba Jehoramu jade tọ̀ Jehu, ọmọ Nimṣi, ẹniti Oluwa fi ororo yàn lati ké ile Ahabu kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní gbogbo ìgbà ìbẹ̀wò Áhásáyà sí Jórámí, Ọlọ́run mú ìṣubú Áhásáyà wá. Nígbà tí Áhásáyà dé, ó jáde lọ pẹ̀lú Jórámì láti lọ bá Jéhù ọmọ Nímísì, ẹni tí OLÚWA ti fi àmì òróró yàn láti pa ìdílé Áhábù run.