2 Chronicles 23:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní kí àwọn eniyan náà dúró, kí wọn máa ṣọ́ ọba, olukuluku pẹlu ohun ìjà lọ́wọ́. Wọ́n tò láti ìhà gúsù ilé náà títí dé ìhà àríwá, ati ní àyíká pẹpẹ ati ti ilé náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tò gbogbo awọn enia tì ọba kakiri olukuluku pẹlu ohun ijà rẹ̀ li ọwọ rẹ̀, lati apa ọtún ile na titi de apa òsi ile na, lẹba pẹpẹ ati lẹba ile na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó mú gbogbo àwọn ọkùnrin wà ní ipò ìdúró pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, yí ọba ká ní ẹ̀bá pẹpẹ àti ilé OLÚWA láti ìhà gúsù sí ìhà àríwa ilé OLÚWA.