2 Chronicles 23:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jehoiada bá mú Joaṣi jáde, ó gbé adé lé e lórí, ó fún un ní ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi Joaṣi jọba, Jehoiada alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi àmì òróró yàn án lọ́ba. Gbogbo eniyan hó pé, “Kí ọba pẹ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn mu ọmọ ọba jade wá, nwọn si fi ade fun u ati iwe ẹri na, nwọn si fi i jọba: Jehoiada ati awọn ọmọ rẹ̀ si fi ororo yàn a, nwọn si wipe, Ki ọba ki o pẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhóiádà àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; Wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!”