2 Chronicles 23:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jehoiada bá rán àwọn ọ̀gágun ọmọ ogun ọgọrun-un pé, “Ẹ fà á síta láàrin àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó bá tẹ̀lé e, ẹ pa á.” Nítorí àwọn alufaa ní kí wọ́n má pa á ninu tẹmpili OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jehoiada alufa mu awọn olori ọrọrun ani awọn olori ogun na jade, o si wi fun wọn pe, Ẹ mu u jade kuro ninu ile sẹhin àgbala: ẹni-kẹni ti o ba si tọ̀ ọ lẹhin, ni ki a fi idà pa. Nitori alufa wipe, Ẹ máṣe pa a ninu ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéhóiádà àlùfáà mú àwọn alákóso ọrọrún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé: “Mú un jáde wá láàrin àwọn ọgbà, kí ẹ sì pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀le.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má se paá nínú ilé OLÚWA.”