2 Chronicles 23:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jehoiada yan àwọn aṣọ́nà fún ilé OLUWA, lábẹ́ àkóso àwọn alufaa, ọmọ Lefi, ati àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi ti ṣètò láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, pẹlu àjọyọ̀ ati orin, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣètò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jehoiada si fi iṣẹ itọju ile Oluwa le ọwọ awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ti Dafidi ti pin lori ile Oluwa, lati ma ru ẹbọ ọrẹ sisun Oluwa, bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, pẹlu ayọ̀ ati pẹlu orin lati ọwọ Dafidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, Jéhóiádà tẹ àwòrán ilé OLÚWA sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Leì ẹni tí Dáfídì ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé OLÚWA láti tẹ ọrẹ sísun ti OLÚWA bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mósè. Pẹ̀lú ayọ̀ Àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti pàsẹ.