2 Chronicles 23:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo wọn pàdé ninu ilé Ọlọrun, wọ́n sì bá ọba dá majẹmu níbẹ̀. Jehoiada wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó! Ọmọ ọba nìyí, ó tó àkókò láti fi jọba nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ṣe pé ìran Dafidi ni yóo máa jọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ijọ enia si ba ọba dá majẹmu ni ile Ọlọrun. O si wi fun wọn pe, Kiyesi i, ọmọ ọba ni yio jọba, gẹgẹ bi Oluwa ti wi niti awọn ọmọ Dafidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ìpéjọ dá májẹ̀mú pẹ̀lú ọba ní ilé Ọlọ́run. Jéhóiádà wí fún wọn pé, “Ọmọkùnrin ọba yóò jọba, bí OLÚWA ti ṣèlérí nípa àwọn àtẹ̀lé Dáfídì.