2 Chronicles 23:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ohun tí ẹ óo ṣe nìyí: nígbà tí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi, ìdámẹ́ta ninu wọn yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi li ohun ti ẹnyin o ṣe; Idamẹta nyin yio wọle li ọjọ isimi, ninu awọn alufa ati ninu awọn ọmọ Lefi, ti yio ṣe adena iloro;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsinyìí èyí ni ohun tí ó yẹ kí ó ṣe: Ìdámẹ́ta àlùfáà yín àti àwọn ará Léfì tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi ni kí ó bojútó àwọn ìlẹ̀kùn.