2 Chronicles 23:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọnú ilé OLUWA, àfi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn lè wọlé nítorí pé wọ́n mọ́. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ó kù gbọdọ̀ pa àṣẹ OLUWA mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o wọ̀ ile Oluwa wá, bikoṣe awọn alufa, ati awọn ti nṣe iranṣẹ fun awọn ọmọ Lefi: nwọn o wọle, nitori mimọ́ ni nwọn: gbogbo awọn enia yio si ṣọ́ ẹṣọ́ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé OLÚWA yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítori tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó ṣọ ohun tí OLÚWA ti yàn fún wọn.