2 Chronicles 24:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn Lefi bá gbé àpótí náà wá fún àwọn òṣìṣẹ́ ọba, tí wọ́n sì rí i pé owó pọ̀ ninu rẹ̀, akọ̀wé ọba ati aṣojú olórí alufaa yóo da owó kúrò ninu àpótí, wọn yóo sì gbé e pada sí ààyè rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe ní ojoojumọ, wọ́n sì rí ọpọlọpọ owó kó jọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati akokò de lati mu apoti na wá sọdọ olutọju iṣẹ ọba nipa ọwọ awọn ọmọ Lefi, nigbati nwọn si ri pe, owo pọ̀, akọwe ọba ati olori ninu awọn alufa a wá, nwọn a si dà apoti na, nwọn a mu u, nwọn a si tun mu u pada lọ si ipò rẹ̀. Bayi ni nwọn nṣe li ojojumọ, nwọn si kó owo jọ li ọ̀pọlọpọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà kígbà tí a bá gbé àpótí wọlé láti ọwọ́ àwọn ará Léfì sí ọwọ́ àwọn ìjòyè ọba, tí wọ́n bá sì rí wí pe owó ńlá wà níbẹ̀ àwọn akọ̀wé ọna àti ìjòyè olórí àlùfáà yóò wá láti kó owó rẹ̀ kúrò, wọn yóò sì dá a padà sí àyè rẹ̀. Wọ́n ṣe èyí déédéé, wọ́n sì kó iye owó ńlá.