2 Chronicles 24:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n tún ilé OLUWA náà ṣe tán, wọ́n kó owó tí ó kù pada sọ́dọ̀ ọba ati Jehoiada. Wọ́n fi owó náà ṣe àwọn ohun èlò fún ìsìn ati ẹbọ sísun ní ilé OLUWA, ati àwo fún turari ati ohun èlò wúrà ati fadaka. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé OLUWA lojoojumọ, ní gbogbo àkókò Jehoiada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si pari rẹ̀ tan, nwọn mu owo iyokù wá si iwaju ọba ati Jehoiada, a si fi i ṣe ohun-elo fun ile Oluwa, ani ohun-elo fun ìsin ati fun ẹbọ, pẹlu ọpọ́n, ani ohun-elo wura ati fadakà. Nwọn si ru ẹbọ sisun ni ile Oluwa nigba-gbogbo ni gbogbo ọjọ Jehoiada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sì parí rẹ̀ tán, wọ́n mú owó ìyókù wá sí iwájú ọba àti Jéhóíádà, a sì fi ohun èlò fún ilé OLÚWA, àní ohun èlò fún ìsìn àti fún ẹbọ pẹ̀lú ọpọ́n, àni ohun èlò wúrà àti fàdákà. Wọ́n sì ń rú ẹbọ sísun ní ilé OLÚWA nígbà gbogbo ní gbogbo ọjọ́ Jéhóiádà.